Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 428: Jésù Ní, Gb' Ojú Rẹ Sókè
Lift Up Your Eyes, The Saviour Says
Jésù ní, Gb' ojú rẹ sókè,
Sí wo ó b' oko ti pọ́n;
Fífún irúgbìn Ọ̀rọ̀ náà
Mú èso rere wá.
Jésù ní, Gb' ojú rẹ sókè,
Sí wo àlìkàmá
Tí ẹ̀kún kíkorò àti
Ìrora Mi mú pọ́n.
Gb' ojú rẹ sókè, 'wọ t' ó wà
Ní àìní ìrètí
Ìránṣẹ́ Jésù n' bí gbogbo
Ń kórè ògó wọ 'lé.
Ẹ jáde lọ olùkórè,
Wò Jésù f' agbára;
Ẹyin yóò padà níkẹ̀yìn
Pẹ̀lú ìtì púpọ̀.