Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 427: Olúwa, Àwa Ọmọ Rẹ, Tún Dé

Lord, We Your Children, Have Come Again

Olúwa, àwa ọmọ Rẹ, tún dé.
Láti wá àánú Rẹ;
Ní àjọ̀dún ìsìn ìkórè wa,
Má ṣàì ṣàánú fún wa.

Àánú, Àánú, Àánú, l' a ń fẹ́,
Lọ́wọ́ Rẹ, Bàbá wa ọ̀run;
Jọ̀ọ́ sì fèrèsé ọ̀run Rẹ lónìí
Má ṣàì ṣàánú fún wa.

Jésù Olúwa l' ọjọ́ ayé Rẹ,
Ọb' Aláànú ni O;
Àwọn adẹ́tẹ̀ àti afọ́jú
R' àánú gbà lọ́wọ́ Rẹ.

Àánú, Àánú, Àánú, l' a ń fẹ́,
Lọ́wọ́ Rẹ, Bàbá wa ọ̀run;
Jọ̀ọ́ sì fèrèsé ọ̀run Rẹ lónìí
Má ṣàì ṣàánú fún wa.

L' ọdún yìí; Olúwa àwa, bẹ Ọ
Má jẹ́ kí 'ṣe wọn wá;
K' Ó sì jẹ́ k' a sọwọ́ b' odè padé,
K' ara dé gbogbo wa.

Àánú, Àánú, Àánú, l' a ń fẹ́,
Lọ́wọ́ Rẹ, Bàbá wa ọ̀run;
Jọ̀ọ́ sì fèrèsé ọ̀run Rẹ lónìí
Má ṣàì ṣàánú fún wa.

Má ṣe jẹ́ kí èṣù rí wa, gbé ṣe
Ní gbogb' ọj' ayé wa;
K' Ó tì lẹ̀kún ikú àti àrùn;
Jọ̀ọ́ jẹ́ k' a jẹ́ Tire.

Àánú, Àánú, Àánú, l' a ń fẹ́,
Lọ́wọ́ Rẹ, Bàbá wa ọ̀run;
Jọ̀ọ́ sì fèrèsé ọ̀run Rẹ lónìí
Má ṣàì ṣàánú fún wa.

Olúwa dàrí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wa,
T' àn fi bí Ọ nínú;
Jọ̀ọ́ ṣe àyípadà rere fún wa
K' a lè máa jẹ́ Tire.

Àánú, Àánú, Àánú, l' a ń fẹ́,
Lọ́wọ́ Rẹ, Bàbá wa ọ̀run;
Jọ̀ọ́ sì fèrèsé ọ̀run Rẹ lónìí
Má ṣàì ṣàánú fún wa.

Nígbàt' ìkórè ayé bá parí,
Tó O kó àwa náà jọ;
B' ìkórè sì kún àbá Rẹ ọ̀run
F' àánú tẹ́wọ́ gbà wa.

Àánú, Àánú, Àánú, l' a ń fẹ́,
Lọ́wọ́ Rẹ, Bàbá wa ọ̀run;
Jọ̀ọ́ sì fèrèsé ọ̀run Rẹ lónìí
Má ṣàì ṣàánú fún wa.