Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 426: Olúwa Ìkórè Náà

Lord Of The Harvest

Olúwa ìkórè náà
Ti ń pọn ní gbogb' ayé,
Níb' àwọn ángẹ́lì yóò kó
Ìtí wọn jọ láìpẹ́;
Lò ọwọ́ wa fún 'ṣe Rẹ,
Jẹ́ k' a f' ọkàn fẹ́ Ọ.
Sì lò wọ́n láti mú kí
'Jọba Rẹ yára dé.

Iṣẹ́ pọ̀ ní papa Rẹ,
Aláàgbàṣe kò tó,
F' ìtara mímọ́ àti
Ìgbàgb' ọ̀tún kún wa;
Àwọn ìránṣẹ́ Rẹ ti
F' omijé fún 'rúgbìn,
L' àkókò yìí jẹ́ k' àwa
Pẹ̀lú gbọ́, "Ó ṣeun".

Kríst' ràn wa láti ṣiṣẹ́
Nín' ọgb' àjàrà Rẹ;
Ó tẹ́ wa lọ́rùn láti
Ṣiṣẹ́ púpọ̀ fún Ọ;
A kò fẹ́ oyà míràn
Ju pé kí a lè ní
Ipa nínú iṣẹ́ ńlá
Mímú 'jọba Rẹ dé.