Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 423: A F' Ọpẹ́ F' Ọlọ́run
Now Thank We All Our God
A f' ọpẹ́ f' Ọlọ́run,
Pẹ̀l' ọkàn, àt' ohùn wa
Ẹni t' ó s' ohun ńlá.
Nínú Ẹni t' ayé ń yọ;
Ẹni t' ó búkún wa
Ní gbogbo ọ̀nà wa
Ẹ̀bùn 'fẹ́ àìníyẹ,
Lónìí, ó jẹ́ tiwa.
Ọba Oníb' ore
Má fi wa sílẹ̀ láéláé
Ayọ̀ tí kò l' òpin
Oùn 'búkún yóò jẹ́ ti wa;
Pa wa mọ́ n' nú oore,
Tọ́ wa gbà a bá dààmú,
Yọ wa nínú ibi
L' ayé àti l' ọ̀run.
Ọpẹ́ àti ìyìn
Fún Ọlọ́run Bàbá wa
Àt' Ọmọ tó jọba
Pẹ̀lú wọn l' òkè ọ̀run
Ọlọ́run àìlópin
T' ayé àt' ọ̀run ń yìn
Gẹ́gẹ́ bó ti wà rí,
Bẹ́ẹ̀ ni yóò wà láéláé.