Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 422: Bàbá Ọ̀run Wà Pẹ̀lú Wa

Heavenly Father Lead Us

Bàbá ọ̀run wà pẹ̀lú wa,
Nínú ìrúmí ayé;
Sọ wa, tọ́ wa sì pa wa mọ́,
'Tòr' a kò ní 'ránwọ́ míì;
Alábùkún ni àwa jẹ́,
B' Ọlọ́run jẹ́ Bàbá wa.

Olùgbàlà dàríjì wa,
'Wọ mọ̀ gbogb' àìlera wa;
'Wọ ti rìn 'nà yí ṣáájú wa
Wọ sì mọ̀ iníra rẹ̀;
Ìwọ nìkan nínú ààrẹ̀
L' Ó là àginjù yìí ja.

Ẹ̀mí ọ̀run sọ kalẹ̀ wá,
F' ayọ̀ ọ̀run k' ọkàn wa;
Jẹ́ kí ìfẹ́ àt' òkè wá,
Dàpọ̀ mọ́ adùn l' ayé;
Gbà t' Ó ń pèsè, t' Ó sì ń tọ́ wa,
Kò s' ohun lè b' ayọ̀ wa jẹ