Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 420: Máa Tọ́jú Wa Bàbá Ọ̀run

Lead Us Heavenly Father

Máa tọ́jú wa Bàbá ọ̀run,
Láàrín 'dààmú ayé yìí;
Pa wa mọ́ kó o sì máa bò wa,
A kò n' ìránwọ́ míràn;
Ṣùgbọ́n gbogbo 'búkún l' a a ní,
B' Ọlọ́run jẹ́ Bàbá wa.

Olùgbàlà, dàríjì wa,
Ìwọ ṣàá m' àìlera wa;
'Wọ ti rìn ayé ṣáájú wa,
'Wọ ti mọ̀ 'ṣe inú rẹ̀;
B' Ẹn' ìkàánú àt' aláàrẹ̀,
L' Ó ti là 'ginjù yí ja.

Ẹ̀mí Ọlọ́run, Sọ kalẹ̀,
F' ayọ̀ ọ̀run k' ọkàn wa;
K' ìfẹ́ dàpọ̀ mọ́ ìyà wa,
Àt' adùn tí kì í sù ní;
Bá a bá pèsè fún wa báyìí,
Kí l' ó lè mí 'simi wa?