Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 42: Jésù Búkún Wa

O Saviour Bless Us

Jésù búkún wa ká a tó lọ;
Gbìn Ọ̀rọ̀ Rẹ sí àyà wa;
Mú k' ọkàn wa t' ó lọ wọ́wọ́
Kún fún ìfẹ́ tí ó gbóná,
N' ìgbà aáyè àt' ikú wa,
Jésù, jọ̀wọ́! ṣe 'mọ́lẹ̀ wa.

Ọjọ́ lọ tán, ilẹ̀ sì sù,
Ìwọ sì ṣírò ìwà wa;
Ìṣẹ́gun díẹ̀ ni a ní,
Ìgbà púpọ̀ l' á sì ṣubú.
N' ìgbà aáyè àt' ikú wa,
Jésù, jọ̀wọ́! ṣe 'mọ́lẹ̀ wa.

Olúwa jọ̀ ọ́ gbà wá sílẹ̀
Pátápátá lọ́wọ́ ìbí;
Búkún wa jù t' ìṣáájú lọ,
Pẹ̀lú àlááfíà ọkàn
N' ìgbà aáyè àt' ikú wa,
Jésù, jọ̀wọ́! ṣe 'mọ́lẹ̀ wa.

Fún wa l' ayọ̀ oùn dàríjì
Ọm'nira àt' ẹ̀rù mímọ́.
Ọkàn relẹ̀ láìlábàwọ́n
Ọkàn tí ó fẹ́ dàbí Rẹ̀.
N' ìgbà aáyè àt' ikú wa,
Jésù, jọ̀wọ́! ṣe 'mọ́lẹ̀ wa.

A ń bẹ Ọ f' àwọn tá a fẹ́ràn
Aláìní àti ẹlẹ́ṣẹ̀;
Jẹ́ k' àánúu Rẹ mú 'nú wa dùn
Ìwọ l' ohun gbogbo fún wa.
N' ìgbà aáyè àt' ikú wa,
Jésù, jọ̀wọ́! ṣe 'mọ́lẹ̀ wa