Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 417: Èm' Ó Tẹ́tẹ́ Wá Olúwa

I Will Early Seek The Saviour

Èm' ó tẹ́tẹ́ wá Olúwa,
Èmi ó kọ́ nípa Rẹ;
Èmi yóò tẹ̀ lé 'pàṣẹ Rẹ,
Èmi yóò rìn 'nà híhà.

Tòr' ó fẹ́ mi, A! ó fẹ́ mi,
Jésù fẹ́ mi, mo mọ̀ bẹ́ẹ̀;
Jésù fẹ́ mi, Ó kú fún mi,
'Tòr' èyí ni mo ṣe fẹ́ E.

Èm' ó lọ sí 'bi t' ó ràn mi,
Ń kò kéré jù láti lọ
L' ojú ọ̀nà 'bít' Ó tọ́ mi,
Mo tó láti mọ̀ 'fẹ́ Rẹ.

Tòr' ó fẹ́ mi, A! ó fẹ́ mi,
Jésù fẹ́ mi, mo mọ̀ bẹ́ẹ̀;
Jésù fẹ́ mi, Ó kú fún mi,
'Tòr' èyí ni mo ṣe fẹ́ E.

Ó ń dúró ní ẹnu 'lẹ̀kún
Ìgbàlà kúrò n' ẹ̀ṣẹ̀;
N ó kànkún tòr' Ó ṣe 'lérí
Yóò gbọ́, yóò jẹ́ kí n wọlé

Tòr' ó fẹ́ mi, A! ó fẹ́ mi,
Jésù fẹ́ mi, mo mọ̀ bẹ́ẹ̀;
Jésù fẹ́ mi, Ó kú fún mi,
'Tòr' èyí ni mo ṣe fẹ́ E.