Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 414: Mọ́kàndínlógóòrún Dùbúlẹ̀ Jẹẹ
There Were Ninety And Nine
Mọ́kàndínlógóòrún dùbúlẹ̀ jẹẹ,
Lábẹ́ oòjì nín' àgbo
Ṣùgbọ́n ọkan jẹ lọ s' ór' òkè
Jìnà s' ìlẹ̀kún wúrà;
Jìnà rere lór' òkè ṣíṣà,
Jìnà rere s' Olùṣàgùtàn,
Jìnà rere s' Olùṣàgùtàn.
"'Mọ́kàndínlógóòrún Tire l' èyí
Jésù, wọ́n kò tó fún Ọ?"
Olùṣàgùtàn dáhùn,
"Tèmi yìí ti ṣako lọ l' ọ̀dọ̀ Mi;"
Bí ọ̀nà tilẹ̀ rí palapala,
N ó w' àginjù lọ w' àgùtàn mi,
N ó w' àginjù lọ w' àgùtàn mi.
Ọkan nín' àwọn t' a a rà padà,
Kò mọ̀ jíjìn omi náà;
Àti órù dúdú tí Jésù kọjá
Kò tó r' àgùtàn Rẹ hẹ;
L' àginjù rere l' Ó gbọ́ 'gbé rẹ̀
Ó ti rẹ̀ ẹ tán, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kú,
Ó ti rẹ̀ ẹ tán, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kú
"Níbo ni ẹ̀jẹ̀ ni tí ń kan wá,
T' ó f' ọ̀nà ór' òkè hàn?'
A tà á sílẹ̀ f' ẹnìkan t' ó ṣako,
K' Olùṣàgùtàn tó mú u padà
"Jésù, kíl' ó gun mi níbẹ̀ bẹ́ẹ̀?"
"Ẹ̀gún púpọ̀ l' ó gun mi níbẹ̀"
"Ẹ̀gún púpọ̀ l' ó gun mi níbẹ̀"
Ṣùgbọ́n ní gbogbo orí òkè
Àti lórí àpáta,
Ìgbé, t' a d' òkè ọ̀run wí pé,
"Yọ, mo r' àgùtàn mi hẹ!"
Àwọn Ángẹ́lì ń kọrin yí 'tẹ́ ká
"Yọ, Jésù m' ohun Tire padà!"
"Yọ, Jésù m' ohun Tire padà!"