Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 410: 'Wọ Ìmọ́lẹ̀ Láàrín Òòkùn Ayé
Lead Kindly Light
'Wọ Ìmọ́lẹ̀ láàrín òòkùn ayé
Máa sìn mi lọ.
Òkùnkùn sù, mo sì jìnà s' ilé;
Máa sìn mi lọ.
Tọ́ 'ṣísẹ̀ mi: ohun ẹ̀yìn ọ̀la
Èmi kò bèèrè; 'ṣísẹ̀ kan tó fún mi.
Nígbà kan rí, èmi kò bẹ Ọ pé;
Bẹ́ẹ̀ ni ń kò fẹ́ Ọ;
Ṣùgbọ́n nígbà yí
Máa sìn mi lọ
Àfẹ́ ayé ni mo ti ń tọ lẹ́yìn;
Ṣùgbọ́n Jésù, má rántí Ìgbà ni.
Ipa Rẹ l' ó ti ń dì mí mú,
yóò sì máa sìn mi lọ;
Nínú ere àti yangi ayé,
Máa sìn mi lọ.
Títí èm' ó fi rí àwọn wọ̀n-ni
Tí m ó fẹ́ tí wọ́n ti f' ayé sílẹ̀.