Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 41: B' Ojìjì Alẹ́ Ti Tún Dé
Again as Evening's Shadow Falls
B' ojìjì alẹ́ ti tún dé,
A pé jọ s' ilé mímọ́ yìí;
Orin àt' àdúrà alẹ́
Ń' gòkè ní ìdàpọ̀ mímọ́
Jẹ́ k' ọkàn tí ń wá 'dàndè
Lè r' àlááfíà Ọlọ́run;
Jẹ́, k' orin àt' àdúrà yìí.
M' ẹ̀dùn àt' àníyàn wọn lọ.
Ọlọ́run, 'Wọ l' á wolé fún,
'Wá dúró láàárín ojìjì;
Jẹ́ k' ìparorò wa j' òótọ́
Kí orin wa sì dùn rán-in rán-in.
A lè padé 'rúmí ayé,
A kò lè máa wà lójú kan;
Ṣùgbọ́n n' ibí kókó ẹ̀mí
L' orin àt' àdúrà yóò wà.