Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 406: Jésù L' Olùṣàgùtàn Mi
The Lord's My Shepherd
Jésù l' Olùṣàgùtàn mi,
Èmi k' yóò s' aláìní;
Níb' odò àt' oko tùtù
L' ó ń f' ọwọ́ Rẹ tọ́ mi.
Ó ń tọ́ mi lọ, ó ń tọ́ mi lọ,
Níbi odò ṣíṣan.
Ó mú k' ọkàn mi tún sójí,
Ó ń tọ́ ìṣísẹ̀ mi;
Ní ipa ọ̀nà odòdó,
Tòrí orúkọ Rẹ.
Ní ipa ọ̀nà odòdó,
Tòrí orúkọ Rẹ.
Bí mo ń rìn n' ojìjì ikú,
Èmi kì ó bẹ̀rù;
'Wọ ń bẹ pẹ̀lú mi, - ọ̀pá Rẹ
Yóò máa tù mi nínú.
'Wọ ń bẹ pẹ̀lú mi, - ọ̀pá Rẹ
Yóò máa tù mi nínú.
Ìwọ tẹ́ tábìlì fún mi
L' ọj' àwọn ọ̀tá mi;
Ìwọ d' òróró s' orí mi,
Ago mi kún, ó ń ṣe.
Ìwọ d' òróró s' orí mi,
Ago mi kún, ó ń ṣe.
Ire àt' àánú Rẹ ń tọ́ mi
Ní gbogbo ayé mi;
N ó sì fi ilé Ọlọ́run
Ṣe 'búgbé mi láéláé.
N ó sì fi ilé Ọlọ́run
Ṣe 'búgbé mi láéláé.