Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 405: Jésù L' Olùṣàgùtàn Mi, Èmi K' Yóò S' Aláìní
The Lord's My Shepherd; I'll Not Want
Jésù l' Olùṣàgùtàn mi,
Èmi k' yóò s' aláìní;
Níb' odò àt' oko tùtù
L' ó ń f' ọwọ́ Rẹ tọ́ mi.
Ó mú k' ọkàn mi tún sójí,
Ó ń tọ́ ìṣísẹ̀ mi;
Ní ipa ọ̀nà odòdó,
Tòrí orúkọ Rẹ.
Bí mo ń rìn n' ojìjì 'kú,
Èmi kì ó bẹ̀rù;
'Wọ ń bẹ pẹ̀lú mi, - ọ̀pá Rẹ
Yóò máa tù mi nínú.
Ìwọ tẹ́ tábìlì fún mi
Lọj' àwọn ọ̀tá mi;
Ìwọ d' òróró s' orí mi,
Ago mi kún, ó ń ṣe.
Ire àt' àánú Rẹ ń tọ́ mi
Ní gbogbo ayé mi;
N ó sì fi ilé Ọlọ́run
Ṣe 'búgbé mi láéláé.