Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 404: Odì Ńlá Ni Ọlọ́run Wa

A Mighty Fortress Is Our God

Odì ńlá ni Ọlọ́run wa,
Àábò tí kò lè yẹ láè,
Òun n' ìránwọ́ wa n' nú ìgbì
Omi t' ó fẹ́ borí wa.
Síbẹ̀ ọ̀tá wa ni
Fẹ́ ṣiṣe ibi rẹ̀,
Ó ní ọgbọ́n púpọ̀,
Ó sì kún fún 'wà 'kà,
Kò s' elégbé rẹ̀ l' ayé.

Ìbáṣep' a kò l' Ẹni tí
Ọlọ́run yàn pẹ̀lú wa;
Bí a bá ja fún ara wa,
Àwa kì yóò lè ṣẹ́gun,
'Wọ ha mọ̀ Ẹni náà?
Krístì Olúwa ni,
Olúwa ọm' ogun ni
Òun kìí yípadà,
Ó sì ní láti ṣẹ́gun

Bí ayé tó kún fún ìkà
Fẹ́ láti ṣe wa ni ibi;
A k' yóò bẹ̀rù tòr' Ọlọ́run
Yóò m' oòtọ́ Rẹ ṣe 'nú wa;
B' èṣù tilẹ̀ ń halẹ̀,
Àwa kì yóò bẹ̀rù;
A ó fara dà 'jà rẹ̀
Ìṣubú rẹ̀ dájú
Tòr' Ọba wa ti ṣẹ́gun.

Ọ̀rọ̀ Rẹ ju agbár' ayé
Ọ̀rọ̀ náà yóò dúró gbọ̀nìn;
Tiwa l' ẹ̀mí àt' oor' ọ̀fẹ́
L' ọlá Olùgbèjà wa;
K' ara oùn iní lọ,
Àt' ara ikú yìí;
Ara ni wọ́n lè pa,
Ọr' Ọlọ́run wa laé.
Ìjọba Rẹ wà láéláé.