Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 401: Pè Jèhófà N' Ìgbàlà Rẹ

Call Jehovah Thy Salvation

Pè Jèhófà n' ìgbàlà rẹ
Simi lábẹ́ Ojìjì Rẹ
Máa gbé níbi ìkọ̀kọ̀ Rẹ,
Láìbẹ̀rù tàbí fọ̀yà;
Kò s' ohun tí yóò dẹ̀rù bà ọ,
'Wọ k' yóò bẹ̀rù ìdẹ̀kùn,
Kò s' ibi t' yóò pa ọ lára,
L' àlàáfíà títí laé.

Láàrín ọkọ̀ tí ń fò l' ọ̀sán-an,
Nín' àjàkalẹ̀ àrùn
Nínú àrùn tí ń rìn l' órù,
Ọlọ́run yóò j' àábò rẹ
Má bẹ̀rù àpò tí ń paní,
Bí ọ̀pọ̀ tilẹ̀ ń ṣubú,
Ọkàn rẹ yóò rí àánú gbà,
B' ẹgbẹ̀gbẹ̀rún tilẹ̀ ń kú.

Tòrí ìwọ ti fi gbogbo
Ọkàn rẹ fẹ́ Ọlọ́run,
Pẹ̀lú ìyè àábò Rẹ ni
Yóò pa ọ mọ́ lát' ọ̀run;
Ké pè E nínú ìpọ́njú rẹ,
Yóò gbọ́, yóò sì gbà ọ là;
Níhìn a ó rí ìpọ́njú,
Adé oùn 'yè wà l' ọ̀run.