Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 400: Olúwa Mo Ń Ṣàfẹ́rí Rẹ
Blessed Lord How Much I Need Thee
Olúwa mo ń ṣàfẹ́rí Rẹ,
Ẹlẹ́ṣẹ̀, òsì, àrẹ̀;
Jọ̀ọ́ dì mí mú kó O sì tọ́ mi,
N' ó ríran, n ó l' agbára.
'Gbà gbogbo, 'gbà gbogbo,
Olúwa mo ń ṣàfẹ́rí Rẹ,
'Gbà gbogbo, 'gbà gbogbo,
Jésù gbà mi n' 'gbà gbogbo.
F' aṣọ ìwà 'rẹ̀lẹ̀ bò mi,
Tèmi l' àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀;
Kọ́ mi kí n lè m' àìlera mi,
Kí n lè l' agbára t' ọ̀run.
'Gbà gbogbo, 'gbà gbogbo,
Olúwa mo ń ṣàfẹ́rí Rẹ,
'Gbà gbogbo, 'gbà gbogbo,
Jésù gbà mi n' 'gbà gbogbo.
Kò s' ewu b' Ìwọ bá ń tọ́ mi,
N ó ṣubú láì tẹ̀lé Ọ,
Rìn pẹ̀lú mi l' ay' òsì yìí
'Wọ ni 'yè oùn 'mọ́lẹ̀ mi.
'Gbà gbogbo, 'gbà gbogbo,
Olúwa mo ń ṣàfẹ́rí Rẹ,
'Gbà gbogbo, 'gbà gbogbo,
Jésù gbà mi n' 'gbà gbogbo.
Èyí t' ó wù k' ọ̀la mú wá,
Ìbàá jẹ́ 'rẹ tàb' ibi;
Ọkàn mi yóò fara mọ́ Ọ;
'Wọ n' Ìtùnú ọkàn mi.
'Gbà gbogbo, 'gbà gbogbo,
Olúwa mo ń ṣàfẹ́rí Rẹ,
'Gbà gbogbo, 'gbà gbogbo,
Jésù gbà mi n' 'gbà gbogbo.