Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 40: Ọjọ́ Oní Kọjá Lọ

The Day Is Past and Over

Ọjọ́ oní kọjá lọ;
A dúpẹ́, Olúwa;
Jọ̀ọ́ gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀
Ní wákàtí òru;
Jésù, jọ̀ọ́ f' ìṣọ́ Rẹ̀ ṣọ́ wa,
Sì mú wa là òru yìí jà.

Ayọ̀ oní kọjá lọ;
A gb' ọkàn wa s' òkè,
Jọ̀ọ́ má jẹ́ k' á n' ìkọ̀sẹ̀
Ní wákàtí òru;
Jésù, jọ̀ọ́ fún wa n' ìmọ́lẹ̀,
Sì mú wa là òru yìí jà.

Láàláà oní kọjá lọ;
A fi orin yìn Ọ;
Jọ̀ọ́, má jẹ́ k' á rí ewu,
Ní wákàtí òru;
Jésù jọ̀ọ́ f' ìṣọ́ Rẹ̀ ṣọ́ wa,
Sì mú wa là òru yìí jà.

S' Olùpamọ́ wa, Bàbá,
N' tórí Ìwọ l' ó mọ̀
Gẹ́gẹ́ b' ewu ti pọ̀ tó;
Tí a ó bá pàdé;
Jésù Olùfẹ́, gbọ́ tiwa,
Sì mú wa là gbogbo wọn jà.