Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 4: Ohun Gbogbo L' Ó Ń Yìn Ọ
All Things Praise Thee
Ohun gbogbo l' ó ń yin Ọ:
Ọ̀run, ayè, àt' òkun
A dá wọn fún ògo Rẹ,
Ki titóbi ọlá Rẹ,
Mú gbogb' ènìyàn sin Ọ́;
K' áwa náà lè máa yin Ọ́
Ohun gbogbo n yin In: oru
D' òru ń kọrin ògo Rẹ;
Ohun gbogbo yin In; ọjọ́
Dé ọjọ ń f' ìmọ̀ Rẹ hàn;
Gbogbo igbà l' o ń yin Ọ́;
Jẹ́ ká lè bá wọn yin Ọ́.
Ohun gbogbo l'ó ń yin Ọ́;
Ìrì, òjò, ìkùukùu,
Ọṣùmàrè wíw' òòrùn,
Odó ṣíṣan, ìjì nlá,
Ẹ̀rùn, àti òtútù,
Ni ó ń sọ ti ògo Rẹ.
Ohun gbogbo l' ó ń yin Ọ,
Ẹlẹdàá ohun gbogbo,
Ọ̀rọ̀ àt' Èmi Mímó;
Àwa wolé l' ẹṣẹ Rẹ,
Jẹ k' ọkàn wa k' ò yìn Ọ́,
B' ohuń gbogbo ti ń yin Ọ.