Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 399: Kò Tọ́ K' Àwọn Mímọ́ Bẹ̀rù

It Is Not Right For The Saints To Fear

Kò tọ́ k' àwọn mímọ́, bẹ̀rù,
Kí wọ́n sọ 'rètí nù;
'Gbà wọ́n kò rètí 'ránwọ́ Rẹ,
Olùgbàlà yóò dé.

Nígbà tí Abram mú ọbẹ,
Ọlọ́run ní. "Dúró"
Àgbò tí ó wà lọ́hùn-un ni
Yóò dípò ọmọ náà!

Gbà Jónà rí sínú omi,
Kò rò láti yọ mọ́;
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ràn ẹja
T' ó gbé e lọ s' èbúté.

B' irú ipa àt' ìfẹ́ yìí
Ti pọ̀ l' ọ̀rọ̀ Rẹ tó!
Èmi bá máa k' àníyàn mi
Lé Olúwa lọ́wọ́!

Ẹ dúró dé ìránwọ́ Rẹ;
B' ó tilẹ̀ pẹ́, dúró;
B' ìlérí náà tilẹ̀ fà 'lẹ̀
Ṣùgbọ́n kò lè pẹ́ dé.