Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 398: Ìwọ N' Ìpìlẹ̀ Ẹ̀kọ́ Wa

We Build Our School On Thee O Lord

Ìwọ n' ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ wa,
A kọ àìní wa w' ọ̀dọ̀ Rẹ
Ọkàn ìfẹ́, ọ̀rọ̀ ayọ̀,
Èrò pípé iṣẹ́ rere.

Àwa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ l' ojú Rẹ,
A sì ń gbé pọ̀ n' nú ìfẹ́ Rẹ;
M' ẹsẹ̀ wa d' rọ̀ n' nú iṣẹ́ Rẹ,
M' èrò wa dọ́gba pẹ̀lú.

Jẹ́ k' ọwọ́ wa ṣiṣẹ́ rere;
Tọ́ etè wa, sọ ọ di mímọ́,
Bí Ìwọ bá wà pẹ̀lú wa,
A ó jore àt' ọgbà tòótọ́.

A ń yí padà, 'Wọ wà títí;
Olùkọ́ àt' Ọ̀rẹ́ rere,
A ń yí, ṣùgbọ́n, járẹ̀ Jésù
Jẹ́ k' a j' orúkọ Rẹ kalẹ̀.