Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 397: Ìṣòro Wà Yí Wa Ká
Trials Dark On Every Hand
Ìṣòro wà yí wa ká, a kò sí lè mọ ọ̀nà,
Tí Olúwa yóò gbà tọ́ wa dé ilé ìlérí náà,
Ṣùgbọ́n Òun yóò tọ́ wa, a ó tẹ̀lé E d' ojú 'kú,
Gbogbo rẹ̀ ni yóò yé wa nígbòòṣe.
Nígbòòṣe, li òwúrọ̀ náà,
T' Ọm' Ọlọ́run yóò péjọ s' ilé,
Àwa yóò sọ ìtàn bí a ṣe ṣẹ́gun;
Gbogbo rẹ̀ ni yóò yé wa nígbòòṣe.
Ọ̀pọ̀ 'gbà l' a ń ṣe àìní àwọn nkan t' ó yẹ k' a a ní,
Ọkàn wa a sì wúwo, fún 'dààmú oùn 'bànújẹ́;
Ṣùgb' a gbékèl' Olúwa, àti gẹ́gẹ́ b' ọ̀rọ̀ Rẹ,
Gbogbo rẹ̀ ni yóò yé wa nígbòòṣe.
Nígbòòṣe, li òwúrọ̀ náà,
T' Ọm' Ọlọ́run yóò péjọ s' ilé,
Àwa yóò sọ ìtàn bí a ṣe ṣẹ́gun;
Gbogbo rẹ̀ ni yóò yé wa nígbòòṣe.
Ìdánwò àti 'kẹ́kún máa ń bá wa l' àìròtẹ̀lẹ̀,
Ọkàn wa a sì gbọ̀gbẹ̀ fún àṣìṣe wa wọ̀yìí,
A sì wá yà wá l' ẹnu, 'tòr' a ti ṣa ipa wa,
Gbogbo rẹ̀ ni yóò yé wa nígbòòṣe.
Nígbòòṣe, li òwúrọ̀ náà,
T' Ọm' Ọlọ́run yóò péjọ s' ilé,
Àwa yóò sọ ìtàn bí a ṣe ṣẹ́gun;
Gbogbo rẹ̀ ni yóò yé wa nígbòòṣe.