Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 396: Ìdákọ̀rọ̀ Rẹ Ha Dá Ọ Lójú

Will Your Anchor Hold?

Ìdákọ̀rọ̀ rẹ ha dá ọ lójú,
Nínú ìjì búburú ayé yìí?
Gbà t' ó ń fé nín' agbára líle rẹ̀,
Ìdákọ̀rọ̀ rẹ ha dá ọ lójú?

A ní 'dákọ̀rọ̀ kan fún ọkàn
T' ó ń dúró gbọ̀nìn 'gbàt' ìjì bá fé;
A sọ ọ m' àpáta tí kò lè yẹ,
Ó ń dúró sinsin nínú 'fẹ́ Jésù.

T' ó bá d' rọ̀ dáadáa ìgbì kò lè gbé e
'Tòrí ó wà lọ́wọ́ Olùgbàlà;
Ìdákọ̀rọ̀ t' ó simi s' ọwọ́ Rẹ,
Yóò dúró b' ó ti wù k' ìgbì le tó.

A ní 'dákọ̀rọ̀ kan fún ọkàn
T' ó ń dúró gbọ̀nìn 'gbàt' ìjì bá fé;
A sọ ọ m' àpáta tí kò lè yẹ,
Ó ń dúró sinsin nínú 'fẹ́ Jésù.

Ìdákọ̀rọ̀ rẹ ha dá ọ lójú,
Nígbà tí ara ń san t' ẹ̀rù ń bà ọ?
'Gbà tí afẹ́fẹ́ búburú bá ń fé,
'Gbà tí 'jì omi ikú bá ń lù ọ.

A ní 'dákọ̀rọ̀ kan fún ọkàn
T' ó ń dúró gbọ̀nìn 'gbàt' ìjì bá fé;
A sọ ọ m' àpáta tí kò lè yẹ,
Ó ń dúró sinsin nínú 'fẹ́ Jésù.

Ìdákọ̀rọ̀ rẹ ha dá ọ lójú,
'Gbà tí o bá ń mí ẹ̀ẹ́mí ìkẹyìn?
B' ó ti wù kó rí 'wọ kì yóò kùnà,
Bí 'dákọ̀rọ̀ rẹ bá dá ọ lójú.

A ní 'dákọ̀rọ̀ kan fún ọkàn
T' ó ń dúró gbọ̀nìn 'gbàt' ìjì bá fé;
A sọ ọ m' àpáta tí kò lè yẹ,
Ó ń dúró sinsin nínú 'fẹ́ Jésù.

Ojú rẹ yóò ha rí òwúrọ̀ náà,
Èbúté dídan ìlú wúrà náà,
Ìdákọ̀rọ̀ rẹ yóò ha dúró bí,
L' etí bèbè ọ̀run t' ìjì kì í dé?

A ní 'dákọ̀rọ̀ kan fún ọkàn
T' ó ń dúró gbọ̀nìn 'gbàt' ìjì bá fé;
A sọ ọ m' àpáta tí kò lè yẹ,
Ó ń dúró sinsin nínú 'fẹ́ Jésù.