Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 395: A! A Bá N' Ìgbàgbọ́ Oòtọ́
Oh For A Faith
A! a bá n' ìgbàgbọ́ oòtọ́,
B' ọ̀tá tilẹ̀ pọ̀ jù;
Tí kì yóò sá níwájú, àìní àt' òsì
Àìní àti òsì, àìní àti òsì.
Ìgbàgbọ́ tí kì yóò kùn
Fún ọ̀pá ìbàwí,
Ṣùgbọ́n ní ìgbà ìṣòro, 'gbà ṣòro
T' ó gbékèl' Ọlọ́run,
T' ó gbékèl' Ọlọ́run,
Ní ìgbà ìṣòro.
Ìgbàgbọ́ tí ń tàn síwájú,
'Gbàt' ìjì ń ja lóde;
Tí kò bẹ̀rù nígbà ewu, nígbà ewu
Tàbí ṣiyèméjì tàbí ṣiyèméjì.
T' ó fara dà 'bínú ayé,
Tí kò ka ẹ̀gàn sí,
Tí kò lè ń s' okùn ayé, s' okùn ayé,
T' ẹ̀tàn rẹ̀ kò lè mú.
T' ẹ̀tàn rẹ̀ kò lè mú.
Olúwa fún mi n' 'gbàgbọ́ yìí,
Ohun t' ó wù k' ó dé;
N ó n' ìtọwọ́ ayọ̀ ọ̀run, ayọ̀ ọ̀run
Láti ayé yìí lọ, láti ayé yìí lọ.