Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 394: F' Ẹ̀rù Rẹ F' Afẹ́fẹ́

Give To The Winds Your Fears

F' ẹ̀rù rẹ f' afẹ́fẹ́
N' Ìrètí, má dààmú,
Ọlọ́run gbọ́, Ó m' ẹ̀dùn rẹ;
Yóò gb' orí rẹ s' òkè.

Kọ àníyàn rẹ lé E
F' ọ̀nà rẹ lé E lọ́wọ́;
Ẹn' t' Ó l' oòtọ́ àti 'tọ́jú
T' ayé 't' ọ̀run ń júbà.

Gbékèlé Olúwa,
Tẹ́ 'ra mọ́ 'ṣe rere;
Fi 'gbàgbọ́ oùn 'rètí tẹ̀lé E,
Ìwọ yóò sì borí.

F' ara rẹ lé E lọ́wọ́
Jẹ́ k' Ó máa darí rẹ;
Ìwọ yóò sì mọ̀ rírí Rẹ
Bí ọgbọ́n Rẹ ti tọ́.