Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 392: Nígbà T' Àlàáfíà Bá Kún Ọ̀nà Mi
When Peace Like A River Attendeth My Way
Nígbà t' àlàáfíà bá kún ọ̀nà mi
Tí 'bànújẹ́ ń san bí odò,
Ohun t' ó wù kó dé,
Ó kọ́ mi kí n wí pé,
Ó dára, ó dára f' ọkàn mi.
Ó dára... f' ọkàn mi,
Ó dára, Ó dára, f' ọkàn mi.
Ẹ̀ṣẹ̀ mi, Bàbá mo kún f' ọ̀pọ̀ ọpẹ́!
Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi ni Jésù
Kàn m' àgbélébùú,
wọ́n kìí tún ṣe t' èmi,
Yìn Jésù, yìn Jésù, ọkàn mi!
Ó dára... f' ọkàn mi,
Ó dára, Ó dára, f' ọkàn mi.
Jẹ́ k' ìgbà náà yára dé t' a ó r' ojú Rẹ.
T' a ó kà sánmọ̀ bí ẹni,
Ìpè yóò dún Olúwa yóò sọ̀ kalẹ̀;
"A, Àmín" Ó dára, f' ọkàn mi.
Ó dára... f' ọkàn mi,
Ó dára, Ó dára, f' ọkàn mi.