Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 39: Ọ̀gọ́ F' Ọlọ́run L' Alẹ́ Yìí
All Praise To Thee My God This Night
Ọ̀gọ́ f' Ọlọ́run l' alẹ́ yìí,
Fún gbogbo oore ìmọ́lẹ̀;
Sọ mí, Ọba àwọn ọba,
Lábẹ́ ojìjì ìyè Rẹ̀.
Olúwa f' ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí
Nítorí Ọmọ Rẹ lónì
K' èmi lè wà l' àlááfíà,
Pẹ̀lú Ìwọ àti ayé.
Jẹ́ k' ọkàn mi lè sùn lé Ọ,
K' oòrùn dídùn y' ojú mi dé;
Oòrùn tí yóò m' ara mi lè
Kí n' lè sìn Ọ ní òwúrọ̀.
Yìn Ọlọ́run, ìbú oore;
Ẹ yìn In, ẹ̀yin ẹ̀dá ayé,
Ẹ yìn In, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
Yìn Bàbá, Ọmọ, oùn Ẹ̀mí.