Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 388: Nígbà Tí 'Gbì Ayé Yìí Bá Ń Yí Lù Ọ
When Upon Life's Billow You Are Tempest Tossed
Nígbà tí 'gbì ayé yìí bá ń yí lù ọ,
T' ó sì dàbí ẹni pé gbogbo rẹ̀ pín
Kà ìbùkún rẹ, ṣírò wọn l' ọkọ̀ọ̀kan
Iṣẹ́ Olúwa, yóò jẹ́ 'yànu fún ọ.
Kà 'búkún rẹ, kà wọn l' ọkọ̀ọ̀kan,
Kà 'búkún rẹ, wò 'ṣe Ọlọ́run
Kà 'búkún rẹ, kà wọn l' ọkọ̀ọ̀kan,
Ìwọ yóò sì rí iṣẹ́ t' Ọlọ́run ṣe.
Ẹrù àníyàn ha ń w' ọkàn rẹ l' ọ̀run?
Iṣẹ́ t' a a pè ọ sí ha ṣòro fún ọ?
Kà 'búkún rẹ 'yèméjì yóò sì fò lọ,
Orin ìyìn ni yóò sì gb' ẹnu rẹ kan.
Kà 'búkún rẹ, kà wọn l' ọkọ̀ọ̀kan,
Kà 'búkún rẹ, wò 'ṣe Ọlọ́run
Kà 'búkún rẹ, kà wọn l' ọkọ̀ọ̀kan,
Ìwọ yóò sì rí iṣẹ́ t' Ọlọ́run ṣe.
'Gbà t' ó bá ń wò àwọn olóró ayé,
Ronú ọrọ̀ tí Jésù ti ṣèlérí;
Kà ìbùkún rẹ owó kò lè rà wọn,
Ère rẹ l' ọ̀run àt' ilé rẹ l' òkè.
Kà 'búkún rẹ, kà wọn l' ọkọ̀ọ̀kan,
Kà 'búkún rẹ, wò 'ṣe Ọlọ́run
Kà 'búkún rẹ, kà wọn l' ọkọ̀ọ̀kan,
Ìwọ yóò sì rí iṣẹ́ t' Ọlọ́run ṣe.
Nínú gbogbo ayídáyídà ayé,
Má ṣe fọ̀yà, Ọlọ́run tóbi jùlọ;
Kà 'búkún rẹ, àwọn Ángẹ́lì yóò tọ́ ọ
Wọ́n yóò sì ràn ọ lọ́wọ́ títí d' òpin.
Kà 'búkún rẹ, kà wọn l' ọkọ̀ọ̀kan,
Kà 'búkún rẹ, wò 'ṣe Ọlọ́run
Kà 'búkún rẹ, kà wọn l' ọkọ̀ọ̀kan,
Ìwọ yóò sì rí iṣẹ́ t' Ọlọ́run ṣe.