Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 387: Mo Lè Bá Jésù Lọ Sí Ibikíbi
Anywhere With Jesus
Mo lè bá Jésù lọ sí ibikíbi,
Sí 'bít' ó wù k' Ó tọ́ mi sí l' ayé yìí;
Láìsí Rẹ ayọ̀ dídùn yóò dibàjẹ́;
Ibikíbi pẹ̀lú Jésù ń kò fọ̀yà
'Bikíbi, 'bikíbi
Ẹ̀rù kò bà mi;
Mo lè bá Jésù lọ sí ibikíbi.
Pẹ̀lú Jésù, kò kù èmi nìkanṣo,
Ọ̀rẹ́ mi lè dà mi, Òun kò lè dà mi.
Bí Ó tilẹ̀ tọ́ mi sí ibi ẹ̀rù,
Ibikíbi pẹ̀lú Jésù ni 'bi 'yìn.
'Bikíbi, 'bikíbi
Ẹ̀rù kò bà mi;
Mo lè bá Jésù lọ sí ibikíbi.
Èmi lè kú fún Jésù níbikíbi,
'Gbà t' ojìjì ikú bá bò mi mọ́lẹ̀;
Mo mọ̀ pé n ó jí láì tún ṣako lọ mọ́
Pẹ̀lú Jésù, ibikíbi n' ilé mi.
'Bikíbi, 'bikíbi
Ẹ̀rù kò bà mi;
Mo lè bá Jésù lọ sí ibikíbi.