Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 385: Mo Ń Dúró Lé 'Lérí

Standing On The Promises

Mo ń dúró lé 'lérí Krístì Ọba mi,
N ó gbé orin 'yìn Rẹ ga títí ayé
N ó f' ògó f' orúkọ Rẹ l' òkè ọ̀run.
N ó dúró lé 'lérí Ọlọ́run.

Dúró, Dúró,
Mo ń dúró lé ìlérí;
Olùgbàlà mi, Èmí ń dúró
Mo ń dúró lór' ìlérí Ọlọ́run.

Mo ń dúró lór' ìlérí tí kò lè yẹ
Nínú ẹ̀rù àt' ìyèméjì ayé;
Nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èm' ó ṣẹ́gun,
Mo ń dúró lé 'lérí Ọlọ́run.

Dúró, Dúró,
Mo ń dúró lé ìlérí;
Olùgbàlà mi, Èmí ń dúró
Mo ń dúró lór' ìlérí Ọlọ́run.

Ní ìdúró lé 'lérí Rẹ, Olúwa,
Ni mo ti fi gbogbo ìfẹ́ mi fún Ọ
Pẹ̀lú Idà ọ̀rọ̀ Rẹ èm' ó ṣẹ́gun,
Mo ń dúró lé 'lérí Ọlọ́run.

Dúró, Dúró,
Mo ń dúró lé ìlérí;
Olùgbàlà mi, Èmí ń dúró
Mo ń dúró lór' ìlérí Ọlọ́run.