Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 380: Sọ Ọ Fún Jésù

Tell It To Jesus

Ààrẹ̀ mú ọ, ọkàn rẹ ha dààmú?
Sọ ọ fún Jésù, sọ ọ fún Jésù.
'Bànújẹ́ ha dípò ayọ̀ fún ọ?
Sọ ọ fún Jésù nìkan.

Sọ ọ fún Jésù, sọ ọ fún Jésù
Òun l' ọ̀rẹ́ tó dájú;
Kò tún s' ọ̀rẹ́ tàbí 'yẹ̀kan bí Rẹ,
Sọ ọ fún Jésù nìkan.

Àsùn-ì-gbèbè omijé l' ó ń sùn bí?
Sọ ọ fún Jésù, sọ ọ fún Jésù;
'Wọ ha l' ẹ̀ṣẹ̀ t' ẹnìkẹ́ni kò mọ̀?
Sọ ọ fún Jésù nìkan.

Sọ ọ fún Jésù, sọ ọ fún Jésù
Òun l' ọ̀rẹ́ tó dájú;
Kò tún s' ọ̀rẹ́ tàbí 'yẹ̀kan bí Rẹ,
Sọ ọ fún Jésù nìkan.

Ìwọ ń fọ̀yà, 'bànújẹ́ tí ń bọ̀ bí?
Sọ ọ fún Jésù, sọ ọ fún Jésù;
Ìwọ ha ń s' àníyàn f' ọjọ́ ọ̀la?
Sọ ọ fún Jésù nìkan.

Sọ ọ fún Jésù, sọ ọ fún Jésù
Òun l' ọ̀rẹ́ tó dájú;
Kò tún s' ọ̀rẹ́ tàbí 'yẹ̀kan bí Rẹ,
Sọ ọ fún Jésù nìkan.

'Ronú ikú ha ń dẹ̀rù b' ọkàn rẹ?
Sọ ọ fún Jésù, sọ ọ fún Jésù,
O ha ń rètí ìjọba Bàbá rẹ?
Sọ ọ fún Jésù nìkan.

Sọ ọ fún Jésù, sọ ọ fún Jésù
Òun l' ọ̀rẹ́ tó dájú;
Kò tún s' ọ̀rẹ́ tàbí 'yẹ̀kan bí Rẹ,
Sọ ọ fún Jésù nìkan.