Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 378: Bàbá, Mo Nà 'Wọ́ Mi Sí Ọ

Father, I Stretch My Hands To Thee

Bàbá, mo nà 'wọ́ mi sí Ọ
Kò sí ránwọ́ míràn;
Bí Ìwọ bá kúrò l' ọ̀dọ̀ mi,
Níbo l' èmi yóò lọ?

Mo gbà Ọmọ Rẹ ọ̀wọ́n gbọ́,
Fún mi l' agbára Rẹ
Jọ̀wọ́ tán gbogbo àìní mi
Láààkò 'tẹ̀wọ́gbà yìí.

Ìpìlẹ̀ṣẹ̀ Ìgbàgbọ́ mi,
Mo gb' ojú mi sí Ọ;
Fún mi l' ẹ̀bùn Oore-ọ̀fẹ́,
K' èmi mi bàá lè yè.

Ìwọ kò ní jẹ́ k' èmi kú,
Sọ̀rọ̀, k' èmi lè yè;
Níhìn ni èmi yóò dúró,
Fún ẹ̀bùn ẹ̀mí Rẹ.

Ọkàn mi ìbá ti yọ tó,
Bí mo bá r' ojú Rẹ;
Jọ̀ọ́ jẹ́ kí n gbọ́hùn ìyè Rẹ
Kí n sì r' oore-ọ̀fẹ́ Rẹ.

Nísisiyìí mo gbàgbọ́ pé
Jésù ti kú fún mi;
Ó sì ti t' ẹ̀jẹ̀ Rẹ sílẹ̀,
Láti rà mi padà.