Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 377: Olúwa, Bàb' Ẹ̀dá Gbogbo

Dear Lord And Father Of Mankind

Olúwa, Bàb' ẹ̀dá gbogbo,
Dàrí wèrè wa jì;
Dà 'ṣọ ẹwà Rẹ b' ọkàn wa,
K' a a padà s' iṣẹ́ Rẹ l' ọ̀tún;
K' a a fi ọwọ́ yìn Ọ.
K' a a fi ọwọ́ yìn Ọ.

Jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa pé tó bẹ́ẹ̀
T' a a ó gbọ́ ìpè Rẹ
Bí àwọn ara ìgbà ni,
Bí a bá gbọ́ t' Ìwọ ń pè wa
K' a a dìde tẹ̀lé Ọ
K' a a dìde tẹ̀lé Ọ

A! Ìsimi ní Galílì,
'Dakẹ́ jẹ̀ẹ́ l' ór' òkè;
N' bi Jésù kúnlẹ̀ àdúrà,
L' orí ayọ̀ ayérayé;
Èyí t' ìfẹ́ túmọ̀.
Èyí t' ìfẹ́ túmọ̀.

D' omi 'túrà Rẹ s' orí wa,
Títí láálàá yóò pín;
M' àníyàn k' rò n nú ayé wa,
Sì jẹ́ kí ayé wa jẹ́wọ́
Ẹwà 'làáfíà Rẹ,
Ẹwà 'làáfíà Rẹ.

Nínú ọ̀pọ̀ oùn láálàá wa,
B' omi sùúrù fún wa;
Mú ẹ̀mí àf' ẹ̀mí kúrò,
Bá wa sọ̀rọ̀ n' nú afẹ́fẹ́,
Ní ohùn ìtúrà,
Ní ohùn ìtúrà.