Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 376: Rìn Jẹ̀jẹ̀, Rìn Jẹ̀jẹ̀
Be Silent, Be Silent
Pa rọ̀rọ̀, pa rọ̀rọ̀,
A gbọ́ ohùn kan
Pa rọ̀rọ̀, pa rọ̀rọ̀,
Sì p' ọ̀rọ̀ náà mọ́
Rìn jẹ̀jẹ̀, rìn jẹ̀jẹ̀,
Jésù ń bẹ níhìn
Rìn jẹ̀jẹ̀, rìn jẹ̀jẹ̀
Ó ń pè ọ, sún mọ́ ọn.
Pa rọ̀rọ̀, pa rọ̀rọ̀
Ibi mímọ́ ni
Pépé tí ó ń sọ̀rọ̀
Oore Ọ̀fẹ́ Rẹ.
Rìn jẹ̀jẹ̀, rìn jẹ̀jẹ̀,
Jésù ń bẹ níhìn
Rìn jẹ̀jẹ̀, rìn jẹ̀jẹ̀
Ó ń pè ọ, sún mọ́ ọn.
Pa rọ̀rọ̀, pa rọ̀rọ̀
Gb' àdúrà rẹ̀lẹ̀
A ń pín nísiyìí n' nú
Ayọ̀ Edeni
Rìn jẹ̀jẹ̀, rìn jẹ̀jẹ̀,
Jésù ń bẹ níhìn
Rìn jẹ̀jẹ̀, rìn jẹ̀jẹ̀
Ó ń pè ọ, sún mọ́ ọn.