Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 375: Ọ̀rẹ́ Ńlá L' A Ní N' Nú Jésù

What a Friend We Have In Jesus

Ọ̀rẹ́ ńlá l' a ní n' nú Jésù
T' Ó rù gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa!
B' ó ti s' àǹfààní láti mú
Gbogbo nkan t' Ọlọ́run lọ!
Wò 'rù àlàáfíà t' a a ń ṣonù,
Ìrọ̀r' àìnídìí t' a a ń jẹ
N' tòrí a kò mú gbogbo nkan
Tọ Ọlọ́run l' àdúrà

Àwa ha ti ní ìdánwò?
'Yọ̀nú ń bẹ níbikíbi?
Kí a máa tàn 'ni ní sùúrù
Mú u t' Ọlọ́run l' àdúrà.
A lè rí Ọ̀rẹ́ odòdó,
T' ó lè gbé 'bànújẹ́ wa,
Jésù mọ̀ gbogb' àìlera wa,
Mú u t' Olúwa l' àdúrà.

Àwa ṣe aláìlera bí?
Àníyàn bò wa mọ́lẹ̀?
Olùgbàlà ni àábò wa
Mú u t' Olúwa l' àdúrà;
Àwọn ọ̀rẹ́ kọ ọ sílẹ̀?
Mú u t' Olúwa l' àdúrà,
Yóò gbé ọ s' apá àábò Rẹ,
Wò yóò sì rí ìtùnú ń bẹ.