Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 373: Jésù! Olùf' Ọkàn Mi

Jesus, Lover Of My Soul

Jésù! Olùf' ọkàn mi,
Jẹ́ kí n sálà s' àyà Rẹ,
Ṣàá t' ìrúmí sún mọ́ mi
Ṣàá tí ìjì ń fé s' òkè;
Pa mi mọ́ Olùgbàlà,
Títí ìjì ayé yóò pín
Tọ́ mi lọ s' èbúté Rẹ,
Ní kẹyìn gbà ọkàn mi

Àábò míì èmi kò ní
Ìwọ l' ọkàn mi rọ̀ mọ́;
Má f' èmi nìkan sílẹ̀,
Gbà mi, sì tú mi nínú,
Ìwọ ni mo gbékèlé,
Ìwọ n' ìránlọ́wọ́ mi;
Má ṣàì f' ìyè apá Rẹ
D' àábò b' orí àìbò mi.

Kríst' Wọ nìkan ni mo fẹ́,
N' nú Rẹ mo r' ohun gbogbo
Gb' ẹni tó ṣubú dìde,
W' aláìsàn, tọ́ afọ́jú;
Odòdó l' orúkọ Rẹ,
Aláìsòdòdó l' èmi,
Mo kún fún ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀,
Ìwọ kún fún odòdó.

'Wọ l' ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́
Láti fi bò ẹ̀ṣẹ̀ mi;
Jẹ́ kí omi ìwòsàn
Wẹ̀ inú ọkàn mi mọ́;
Ìwọ l' orísun ìyè,
Jẹ́ kí n bù n' nú Rẹ l' ọ̀fẹ́
Rú jade n' nú ọkàn mi,
Sí ìyè àìnípẹ̀kun.