Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 370: Wákàtí Àdúrà Dídùn

Sweet Hour Of Prayer

Wákàtí àdúrà dídùn!
T' ó gbé mi lọ kúrò l' ayé
Lọ 'wájú ìtẹ́ Bàbá mi,
Kí n sọ gbogbo ẹ̀dùn mi fún-Un
Nígbà 'bànújẹ́ àt' àrọ̀
Àdúà l' àábò fún ọkàn mi;
Èmi sì bọ́ lọ́wọ́ Èṣù
Gbà tí mo bá ń gb' àdúà dídùn.

Wákàtí àdúrà dídùn!
Ìyè rẹ̀ yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi
Lọ s' ọd' Ẹni t' ó ṣe 'lérí
Láti búkún ọkàn àdúà;
Bó O ti 'kọ́ mi kí n w' ojú Rẹ,
Kí n gbékèlé E, kí n sì gbàagbọ́
N ó kọ gbogb' àníyàn mi lé E.
Ní àkókò àdúà dídùn.

Wákàtí àdúrà dídùn!
Jẹ́ kí n máa r' ìtùnú rẹ̀ gbà,
Títí n ó fi d' òkè Písgà,
Tí n ó r' ilé mi l' òkèèrè;
N ó bọ́ àgọ́ ara sílẹ̀
N ó gbà ère àìnípẹ̀kun;
N ó kọrin bí mo ti ń fò lọ
Odìgbóòṣe, àdúà dídùn.