Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 37: Wá Bá Mi Gbé
Abide With Me
Wá bá mi gbé! alẹ́ fẹrẹ̀ lẹ tán,
Òkùnkùn ń' sù; Olúwa bá mi gbé
Bí olùrànlọ́wọ́ míràn bá yẹ̀,
Ìrànwọ́ aláìní, wá bá mi gbé.
Ọjọ́ ayé mi ń' sáré lọ s' òpin,
Ayọ̀ ayé ń' kú, ọ̀gọ rẹ ń' wọmí
Àyídà àt' ìbàjẹ́ ni mo ń' rí;
'Wọ tí kì í yípadà wá bá mi gbé.
Mo ń' fẹ́ Ọ rí, ní wákàtí gbogbo;
Kí lo lè ṣẹ́gun Èṣù b' oore Rẹ?
Ta l' ó lè ṣe amọ̀nà mi bí Rẹ?
N' nú 'bànújẹ́ àt' ayọ̀, bá mi gbé!
Pẹ̀lú 'bùkún Rẹ, ẹ̀rù kò bà mí;
Ìbí kò wúwo, ẹkún kò korò;
Ọ̀rọ̀ ikú dà? 'ṣẹ́gun isà dà?
N' ó ṣẹ́gun síbẹ̀, b' Ìwọ bá mi gbé.