Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 369: L' Àkókò F' Àdúrà

Take Time To Be Holy

L' àkókò f' àdúrà, bá Jésù sọ̀rọ̀,
Máa gbé inú Rẹ, sì máa jẹ ọ̀rọ̀ Rẹ:
Máa ràn àwọn ọmọ-Ọlọ́run lọ́wọ́
Máṣe gbàgbé láti wá ìbùkún Rẹ.

L' àkókò f' àdúrà, ayé ń kọjá lọ,
Ní àdúrà 'kọ́kọ́, bá Jésù sọ̀rọ̀;
Nípa wíwò Krístì 'wọ ó dàbí Rẹ,
Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ yóò rí i pé o dàbí Rẹ.

L' àkókò f' àdúrà, fi ṣ' àmọ̀nàrẹ,
Má rìn 'nà ara rẹ, b' ó ti wù kó rí;
N' nú ayọ̀ àt' ẹ̀dùn, tẹ̀l' Ọlọ́run rẹ,
Nínú wíwò Jésù, gbékèl' ọ̀rọ̀ Rẹ.

L' àkókò f' àdúrà, simi l' àyà rẹ;
K' àníyàn rẹ gbogbo l' Olúwa l' ọ́wọ́
Ẹ̀mí Mímọ́ yóò fi ìfẹ́ kún 'nú rẹ,
Títí 'wọ yóò fi yẹ fún 'sìn Rẹ l' òkè.