Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 367: Ìwọ Ìmọ́lẹ̀ Ọkàn Mi
Sun Of My Soul O Saviour dear!
Ìwọ Ìmọ́lẹ̀ ọkàn mi,
Ní ọ̀dọ̀ Rẹ órù kò sí,
Kí 'kùúkùú ayé má bò Ọ́,
Kúrò l' ojú ìránṣẹ́ Rẹ.
Nígbà t' oòrùn alẹ́ dídùn
Bá ń pa ìpẹ̀npẹ̀jú mi dé,
K' èrò mi jẹ́ láti simi;
Laé, l' àyà Olùgbàlà mi.
Bá mi gbé l' oòrọ̀ títí alẹ́
Láì sí Rẹ, èmi kò lè wà;
Bá mi gbé 'gbàt' ilẹ̀ bá ń sù
Èmi kò jẹ́ kú láì sí Rẹ.
Ṣùré fún mi ń gbà tí mo jí
Kí n 'tó m' ohun ayé yìí ṣe;
Kí n lè fẹ́ Ọ títí d' ọ̀run,
Tí n ó sì dé Ìjọba Rẹ