Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 366: Gbà' Jésù Wọ 'Nú Ọkàn Mi
Since Jesus Came Into My Heart
A! àyídá 'yànu ni mo rí l' ayé mi
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi!
Mo ti rí ìmọ́lẹ̀ tí ọkàn mi ti ń wá
'Gbà Jésù wọ 'nú ọkàn mi!
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi,
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi,
Ẹkún rere ayọ̀ sì gbà ọkàn mi kan
'Gbà Jésù wọ 'nú ọkàn mi.
Mo simi, èmi kò ṣako lọ l' àgbo mọ́,
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi!
A sì wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi t' ó pọ̀ bí 'yanrín nù,
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi!
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi,
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi,
Ẹkún rere ayọ̀ sì gbà ọkàn mi kan
'Gbà Jésù wọ 'nú ọkàn mi.
Mo sì ní ìrètí tí ó dúró sinsin,
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi!
Òkùnkùn kò sí lè ṣù bò ọ̀nà mi mọ́,
'Gbà Jésù wọ 'nú ọkàn mi!
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi,
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi,
Ẹkún rere ayọ̀ sì gbà ọkàn mi kan
'Gbà Jésù wọ 'nú ọkàn mi.
Ìmọ́lẹ̀ là fún mi l' àfọ̀nífọ̀jì 'kú
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi!
Ìlẹ̀kún 'bodè rẹ̀ sì ṣí sílẹ̀ fún mi
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi!
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi,
'Gbà' Jésù wọ 'nú ọkàn mi,
Ẹkún rere ayọ̀ sì gbà ọkàn mi kan
'Gbà Jésù wọ 'nú ọkàn mi.