Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 365: Olúwa Ń Kọ Wá Ọrọ̀
Lord I Care Not For Riches
Olúwa ń kọ wá ọrọ̀
Bẹ́ẹ̀ ni ń kọ wá owó;
Èmi ó w' ọ̀nà ọ̀run
N ó wọ 'nú àgbo náà;
Nínú ìwé 'jọba Rẹ,
Tí kò sí l' àbàwọ́n;
Olúwa, jọ̀ọ́ sọ fún mi,
Mo ha l' oókọ níbẹ̀?
Mo ha l' oókọ níbẹ̀
L' ojú ìwé tó ń dán?
Nínú ìwé 'jọba Rẹ
Mo ha l' oókọ níbẹ̀?
Olúwa, ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀.
Bí yanrín etí 'kun
Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ Rẹ, Jésù,
Ó sì ti tó fún mi;
A ti kọ̀wé 'lérí Rẹ
Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí ń dán
B' ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pọn b' odòdó,
Wọ́n yóò fun bí yìnyín.
Mo ha l' oókọ níbẹ̀
L' ojú ìwé tó ń dán?
Nínú ìwé 'jọba Rẹ
Mo ha l' oókọ níbẹ̀?
Ìlú dáradára ni;
Pẹ̀lú 'búgbé 'mọ́lẹ̀,
Àt' àwọn t' a ṣe l' ògó,
Nínú aṣọ funfun;
Níbi t' ẹ̀ṣẹ̀ kò lè wọ,
Láti b' ohun 'rẹ jẹ
T' àwọn ángẹ́lì ń ṣọ́nà,
Mo ha l' oókọ níbẹ̀?
Mo ha l' oókọ níbẹ̀
L' ojú ìwé tó ń dán?
Nínú ìwé 'jọba Rẹ
Mo ha l' oókọ níbẹ̀?