Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 362: Má Ṣe F' Oókọ Jésù Sílẹ̀
Take The Name Of Jesus With You
Má ṣe f' oókọ Jésù sílẹ̀,
Ọm' òsì àt' ìkàánú;
Yóò f' ayọ̀ oùn 'tùnú fún ọ,
Mú U lọ sí ibi gbogbo.
Oókọ yìí... Ti dùn tó!
Fún 'rètí àwọn t' ayé
Oókọ yìí... Ti dùn tó!
Fún Ayọ̀ àwọn t' ọ̀run.
Má ṣe f' oókọ Jésù sílẹ̀,
Àábò nínú ìkẹ̀kùn,
Gbà t' Ìdánwò bá yí ọ ká,
Gbàdú'à lọ́ókọ mímọ́ náà.
Oókọ yìí... Ti dùn tó!
Fún 'rètí àwọn t' ayé
Oókọ yìí... Ti dùn tó!
Fún Ayọ̀ àwọn t' ọ̀run.
A! oókọ Jésù 'yebíye,
Ó f' ayọ̀ kún ọkàn wa,
Apá 'fẹ́ Rẹ gbà wa mọ́ra,
Orin Rẹ sì gb' ẹnu wa!
Oókọ yìí... Ti dùn tó!
Fún 'rètí àwọn t' ayé
Oókọ yìí... Ti dùn tó!
Fún Ayọ̀ àwọn t' ọ̀run.
A ń wọlé l' orúkọ Jésù,
A ń tẹrìba l' ẹsẹ̀ Rẹ,
Ọb' àwọn ọba yóò gb' adé,
'Gbàt' ìrìn wa bá parí.
Oókọ yìí... Ti dùn tó!
Fún 'rètí àwọn t' ayé
Oókọ yìí... Ti dùn tó!
Fún Ayọ̀ àwọn t' ọ̀run.