Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 36: L' Ojú Alẹ́ Gbàt' Oòrùn Wọ̀
At Even When The Sun Was Set
L' ojú alẹ́ gbàt' òòrùn wọ̀,
'Wọ́n gbé abìrùn w' ọ̀dọ̀ Rẹ;
Oníríúrú ni àìsàn wọn,
Ṣùgbọ́n wọ́n f' ayọ̀ lọ 'lé wọn.
L' ẹ̀ẹ̀kan sì b' alẹ́ sì tí ń' lẹ
A wá t' á wá àt' àrùn wa;
Bí a kò tilẹ̀ lè rí Ọ,
Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Ọ wà níhìn-in.
Krístì bá wa wò àrùn wa;
Àwọn míràn ń' ṣààrẹ̀ ọkàn,
Àwọn míràn kò fẹ́ Ọ rí,
Ìfẹ́ àwọn míràn ti sà.
Kò s' ọ̀kan nínú wa t' ó pé
Gbogbo wa sáà ni ẹlẹ́ṣẹ̀;
Àwọn t' ó sì ń' sìn Ọ tòótọ́
Mọ̀ ara wọn ní aláìpé.
Agbár' ọwọ́ Rẹ wà síbẹ̀,
Ọ̀rọ̀ Rẹ kì í wà láìlésọ,
Gbọ́! Ní wákàtí alẹ́ yìí,
Wò wá sàn nínú àrùn wa.