Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 359: Dájúdájú T' Èmi Ni Jésù

Blessed Assurance Jesus Is Mine

Dájúdájú t' èmi ni Jésù,
Ìtọw'́ ògó ọ̀run ti dùn tó!
Ajogún ìjọba t' Ọlọ́run
T' a bí n' Ẹ̀mí Rẹ t' a f' ẹ̀jẹ̀ rà.

Èyí n' ìtàn mi, 'yìí l' orin mi,
Kí n fi ayé mi yìn Olúwa;
Èyí n' ìtàn mi, yìí l' orin mi,
Kí n fi ayé mi yìn Olúwa.

Ìtúùbà pípé, ayọ̀ dídùn,
Ìràn ayọ̀ ńlá hàn fún mi rí;
Àwọn Ángẹ́l' mú sọ̀kalẹ̀ wá
Gbọ́hùn-gbọ́hùn àánú àt' ìfẹ́.

Èyí n' ìtàn mi, 'yìí l' orin mi,
Kí n fi ayé mi yìn Olúwa;
Èyí n' ìtàn mi, yìí l' orin mi,
Kí n fi ayé mi yìn Olúwa.

Ìtúùbà pípé, 'simi dídùn,
N ó simi l' àyà Olùgbàlà;
N ó dúró, n ó sì ṣọ́ ọ̀nà dé E
Títí yóò f' ìfẹ́ kún ọkàn mi.

Èyí n' ìtàn mi, 'yìí l' orin mi,
Kí n fi ayé mi yìn Olúwa;
Èyí n' ìtàn mi, yìí l' orin mi,
Kí n fi ayé mi yìn Olúwa.