Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 358: Jẹ́ K' Ọkàn Wa Máa Kún F' Ayọ̀

Let Our Heart Be Always Cheerful

Jẹ́ k' ọkàn wa máa kún f' ayọ̀,
Ẹ̀ṣe t' a ó fi bànújẹ́,
'Gbàtí Bàbá wa Olùfẹ́,
Ń tọ́jú àwa ọmọ Rẹ?

Kí 'nú wa dùn, kí 'nú wa dùn
Ayọ̀ yí wa káàkiri;
'Tòr' ọ̀nà iṣẹ́ náà kún fún ẹwà,
Kí inú wa ṣàá máa dùn.

K' ọwọ́ jẹ̀jẹ̀ Rẹ máa tọ́ wa,
Bí a bọ́ s' inú ẹ̀ṣẹ̀;
Ó ṣèlérí 'ránwọ́ fún wa,
Ìlérí Rẹ kò lè yẹ.

Kí 'nú wa dùn, kí 'nú wa dùn
Ayọ̀ yí wa káàkiri;
'Tòr' ọ̀nà iṣẹ́ náà kún fún ẹwà,
Kí inú wa ṣàá máa dùn.

'Gbà t' a a bá kọ iṣẹ́ sílẹ̀,
Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ a bá wa;
Ojìjì, t' ó bò orí wa,
Dáwọ́ orin wa dúró.

Kí 'nú wa dùn, kí 'nú wa dùn
Ayọ̀ yí wa káàkiri;
'Tòr' ọ̀nà iṣẹ́ náà kún fún ẹwà,
Kí inú wa ṣàá máa dùn.

A! ènìyàn rere l' ayọ̀,
Ọ̀nà wọn a sì máa dán;
Jẹ́ k' a gbà 'mọ̀ràn ìbùkún,
Kọ ibi, sì fẹ́ ìre.

Kí 'nú wa dùn, kí 'nú wa dùn
Ayọ̀ yí wa káàkiri;
'Tòr' ọ̀nà iṣẹ́ náà kún fún ẹwà,
Kí inú wa ṣàá máa dùn.