Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 357: Ọjọ́ Ńlá L' Ọjọ́ Tí Mo Yàn
O Happy Day! That Fixed My Choice
Ọjọ́ ńlá l' ọjọ́ tí mo yàn
Olùgbàlà l' Ọlọ́run mi;
Ó yẹ kí ọkàn mi máa yọ,
K' ó sì rọ ìhìn náà ká 'lẹ̀.
Ọjọ́ ńlá l' ọjọ́ náà
Tí Jésù wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù;
Ó kọ́ mi kí n máa gbàdúrà,
Kí n máa ṣọ́ra kí n sì máa yọ
Ọjọ́ ńlá l' ọjọ́ náà,
Tí Jésù wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù.
Iṣẹ́ ìgbàlà parí ná
Mo di t' Olúwa mi lónìí;
Òun l' ó pè mí tí mo sì jẹ́,
Mo f' ayọ̀ jẹ́ 'pè mímọ́ náà.
Ọjọ́ ńlá l' ọjọ́ náà
Tí Jésù wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù;
Ó kọ́ mi kí n máa gbàdúrà,
Kí n máa ṣọ́ra kí n sì máa yọ
Ọjọ́ ńlá l' ọjọ́ náà,
Tí Jésù wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù.
Simi ọkàn t' ó ti ṣako,
Máa wò ibi ayọ̀ Mímọ́,
Má ṣe kọ Olúwa sílẹ̀,
Yóò fi ohun rere fún ọ.
Ọjọ́ ńlá l' ọjọ́ náà
Tí Jésù wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù;
Ó kọ́ mi kí n máa gbàdúrà,
Kí n máa ṣọ́ra kí n sì máa yọ
Ọjọ́ ńlá l' ọjọ́ náà,
Tí Jésù wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù.
'Wọ ọ̀run t' ó gbọ́ ẹjẹ́ mi,
Yóò máa tún gbọ́ lójòòjúmọ́
Títí wákàtí ìgbẹ̀yìn,
N ó búkún 'dápọ̀ tó dùn náà.
Ọjọ́ ńlá l' ọjọ́ náà
Tí Jésù wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù;
Ó kọ́ mi kí n máa gbàdúrà,
Kí n máa ṣọ́ra kí n sì máa yọ
Ọjọ́ ńlá l' ọjọ́ náà,
Tí Jésù wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù.
Nígbà t' àwọn ẹ̀rọ Mímọ́
Bá ń bọ̀ lát' ọ̀run wá s' ayé
N ó b' Olùgbàlà mi jọba
N' ilé ayọ̀ náà títí laé
Ọjọ́ ńlá l' ọjọ́ náà
Tí Jésù wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù;
Ó kọ́ mi kí n máa gbàdúrà,
Kí n máa ṣọ́ra kí n sì máa yọ
Ọjọ́ ńlá l' ọjọ́ náà,
Tí Jésù wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù.