Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 354: Ìdápọ̀ Àt' Ayọ̀ Wo Ni Ó Tó
What A Fellowship, What A Joy Divine
Ìdápọ̀ àt' ayọ̀ wo ni ó tó,
Sísimi l' apá ayérayé;
'Búkún àt' àlàáfíà wo l' ó tó
Sísimi l' apá ayérayé.
Ní sísimi,
A bọ́ lọ́wọ́ ẹrù gbogbo
Ní sísimi,
Sísimi, l' apá ayérayé.
Ó dùn púpọ̀ láti rìn 'nà yìí ni
Sísimi l' apá ayérayé.
Wò b' ọ̀nà tí ń dán lójòòjúmọ́, ni
Sísimi l' apá ayérayé.
Ní sísimi,
A bọ́ lọ́wọ́ ẹrù gbogbo
Ní sísimi,
Sísimi, l' apá ayérayé.
Kín ni n bá bẹ̀rù, kí ni n' bá fọ̀yà,
Ní sísimi, l' ap' ayérayé
Mo l' àlàáfíà pẹ̀l' Olúwa, ni
Sísimi l' apá ayérayé.
Ní sísimi,
A bọ́ lọ́wọ́ ẹrù gbogbo
Ní sísimi,
Sísimi, l' apá ayérayé.