Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 353: N Ó Fẹ́ràn Rẹ, 'Wọ Odì Mi

Thee Will I Love, my Strength, my Tower

N ó fẹ́ràn Rẹ, 'wọ odì mi:
N ó fẹ́ràn Rẹ, wò ayọ̀ mi:
N ó fẹ́ràn Rẹ, pátápátá,
N ó fẹ́ràn Rẹ, tòr' iṣẹ́ Rẹ,
N ó fẹ́ràn Rẹ, tít' ọkàn mi,
Yóò fi kún fún ìfẹ́ rere.

'Wọ Oòrùn mi, gbà ọpẹ́ mi,
Fún 'mọ́lẹ̀ Rẹ t' ó fi fún mi;
Gbà ọpẹ́ mi, 'wọ l' ó gbà mi
Lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣọ̀tá mi:
Gbà ọpẹ́ mi, fún ohùn Rẹ
T' ó mú mi yọ lọ́pọ̀lọpọ̀.

N' nú ìré-ije mi l' ayé
Máa ṣe alábòójútó mi;
Fi agbára fún ẹsẹ̀ mi,
Kí n lè t' ẹsẹ̀ m' ọ̀nà rere;
Kí n bá lè f' ipa mi gbogbo,
F' orúkọ Rẹ t' ó l' ògó hàn.

N ó fẹ́ràn Rẹ, 'Wọ adé mi,
N ó fẹ́ràn Rẹ, Olúwa mi;
N ó fẹ́ràn Rẹ, nígbà gbogbo,
L' ọjọ́ ibi, l' ọjọ́ ire,
Gbàtí ọjọ́ ikú bàá dé
N ó fẹ́ràn Rẹ títí láéláé.