Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 350: Kín Fẹ́ Ọ Sí I
More Love To Thee
Kín fẹ́ Ọ sí i, Krístì!
Kí n fẹ́ Ọ sí i;
Gb' àdúrà tí mo ń gbà
Lór' ẹ̀ẹ́kún mi,
Èyí ni ẹ̀bẹ̀ mi;
Kí n fẹ́ Ọ sí i, Krístì!
Kí n fẹ́ Ọ sí i,
kín fẹ́ Ọ sí i!
Lẹ́ẹ̀kan ohun ayé
Ni mo ń tọrọ:
Nísisiyìí, 'Wọ nìkan ni mo ń wá:
Èyí l' àdúrà mi:
Kí n fẹ́ Ọ sí i, Krístì!
Kí n fẹ́ Ọ sí i;
Kí n fẹ́ Ọ sí i!
Jẹ́ kí 'bànújẹ́ dé, àt' ìrora,
Dídùn l' ojíṣẹ́ Rẹ,
Àt' iṣẹ́ wọn;
'Gbà wọ́n ń bá mi kọrin,
Kí n fẹ́ Ọ sí i, Krístì!
Kí n fẹ́ Ọ sí i,
kí n fẹ́ Ọ sí i!
Ń jẹ́, òpin ẹ̀mí mi
Yóò w' ìyìn Rẹ,
Èyí ni yóò jẹ́
Ọ̀rọ̀ 'kẹyìn rẹ̀:
Àdúrà náà yóò jẹ́:
Kí n fẹ́ Ọ sí i; Krístì!
Kí n fẹ́ Ọ sí i,
kí n fẹ́ Ọ sí i!