Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 35: Ọjọ́ Oní Kọjá
Now the Day Is Over
Ọjọ́ oní kọjá
Òru sún mọ́ 'lé,
Ojìjì bò ilẹ̀,
Ilẹ̀ sì ti sù.
Jésù fún aláàárẹ̀
N' ìsímí dídùn,
Pẹ̀lú ìbùkún Rẹ
Pa ojú wa dé.
Nínú gbogbo òru
Jẹ́ k' ángẹ́lì Rẹ̀
F' ìyè dáábo bò mí
Lórí 'búsùn mi.